Joshua 22:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ máa ranti lemọ́lemọ́ láti máa pa gbogbo òfin tí Mose iranṣẹ OLUWA fun yín mọ́, pé kí ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹ máa pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ súnmọ́ ọn, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kìki ki ẹ kiyesara gidigidi lati pa aṣẹ ati ofin mọ́, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin, lati fẹ́ OLUWA Ọlọrun nyin, ati lati ma rìn ni gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀ mọ́, ati lati faramọ́ ọ, ati lati sìn i pẹlu àiya nyin gbogbo ati pẹlu ọkàn nyin gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ sọ́ra gidigidi láti pa àṣẹ àti òfin tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA fi fún yin mọ́. Láti fẹ́ràn OLÚWA Ọlọ́run yín, láti rìn nínú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, láti gbọ́ràn sí àṣẹ rẹ̀, láti dì í mú ṣinṣin àti láti sìn ín pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti gbogbo àyà yín.”