Joshua 22:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ máa kó ọpọlọpọ dúkìá pada lọ sí ilé yín, ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn, fadaka, wúrà, idẹ, irin, ati ọpọlọpọ aṣọ. Ẹ pín ninu ìkógun tí ẹ kó lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá yín fún àwọn arakunrin yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ pẹlu ọrọ̀ pipọ̀ si agọ́ nyin, ati pẹlu ohunọ̀sin pipọ̀, pẹlu fadakà, ati pẹlu wurà, ati pẹlu idẹ ati pẹlu irin, ati pẹlu aṣọ pipọ̀pipọ: ẹ bá awọn arakunrin nyin pín ikogun awọn ọtá nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí pé, “Ẹ padà sí ilẹ̀ ẹ yín pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀ yín, pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn, pẹ̀lú fàdákà, wúrà, idẹ àti irin, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣọ, kí ẹ sì pín ìkógún tí ẹ rí gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta yín pẹ̀lú àwọn arákùnrin yín.”