Joshua 23:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ mọ̀ dájú pé, OLUWA Ọlọrun yín kò ní lé àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi jáde kúrò fun yín mọ́; ṣugbọn wọn óo di ẹ̀bìtì ati tàkúté fun yín, OLUWA yóo sì fi wọ́n ṣe pàṣán tí yóo máa fi nà yín. Wọn óo dàbí ẹ̀gún, wọn óo máa gún yín lójú, títí tí ẹ óo fi parun patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe OLUWA Ọlọrun nyin ki yio lé awọn orilẹ-ède wọnyi jade mọ́ kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ okùn-didẹ ati ẹgẹ́ fun nyin, ati paṣán ni ìha nyin, ati ẹgún li oju nyin, titi ẹ o fi ṣegbé kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé OLÚWA Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹkùn àti tàkúté fún un yín, pàsán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí OLÚWA Ọlọ́run yín ti fi fún yín.