Joshua 23:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nisinsinyii, ó tó àkókò fún mi láti kú, gbogbo yín ni ẹ sì mọ̀ dájúdájú ninu ọkàn yín pé, ninu gbogbo àwọn ohun rere tí OLUWA Ọlọrun yín ṣèlérí fun yín, kò sí èyí tí kò mú ṣẹ. Gbogbo wọn patapata ni wọ́n ṣẹ, ẹyọ kan kò yẹ̀ ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kiyesi i, li oni emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: ényin si mọ̀ li àiya nyin gbogbo, ati li ọkàn nyin gbogbo pe, kò sí ohun kan ti o tase ninu ohun rere gbogbo ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ niti nyin; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ fun nyin, kò si sí ohun ti o tase ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti se kò sí ọ̀kan tí ó kùnà.