Joshua 23:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí OLUWA Ọlọrun yín ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ nípa àwọn nǹkan dáradára tí ó pinnu láti ṣe fun yín, bákan náà ni yóo mú kí gbogbo àwọn nǹkan burúkú tí ó ti ṣèlérí wá sórí yín, títí tí yóo fi run yín patapata lórí ilẹ̀ dáradára tí ó fun yín,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, gẹgẹ bi ohun rere gbogbo ti ṣẹ fun nyin, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ fun nyin; bẹ̃ni OLUWA yio mú ibi gbogbo bá nyin, titi yio fi pa nyin run kuro ni ilẹ daradara yi ti OLUWA Ọlọrun nyin ti fi fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti OLÚWA Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúsẹ, bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.