Joshua 23:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó! Gbogbo ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí a kò tíì ṣẹgun, ati gbogbo àwọn tí a ti ṣẹgun ni mo ti pín fun yín gẹ́gẹ́ bí ogún yín, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti odò Jọdani, títí dé Òkun Mẹditarenia ní apá ìwọ̀ oòrùn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ rántí bí mo ṣe pín ogún ìní fún àwọn ẹ̀yà yín ní ilẹ̀ orílẹ̀ èdè gbogbo tí ó kù; àwọn orílẹ̀ èdè tí mo ti sẹ́gun-ní àárin Jọ́dánì àti Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn.