Joshua 23:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ dúró ṣinṣin kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sinu ìwé òfin Mose. Ẹ kò gbọdọ̀ yẹ ẹsẹ̀ kúrò ninu wọn sí ọ̀tún tabi sí òsì,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ mura gidigidi lati tọju ati lati ṣe ohun gbogbo ti a kọ sinu iwé ofin Mose, ki ẹnyin ki o má ṣe yipada kuro ninu rẹ̀ si ọwọ́ ọtún tabi si ọwọ́ òsi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ jẹ́ alágbára gidigidi, kí ẹ sì sọ́ra láti ṣe ìgbọ́ran sí ohun tí a kọ sí inú Ìwé Ofin Mósè, láìyí padà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.