Joshua 23:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ẹ má baà darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ́kù láàrin yín, kí ẹ má baà máa bọ àwọn oriṣa wọn, tabi kí ẹ máa fi orúkọ wọn búra, tabi kí ẹ máa sìn wọ́n, tabi kí ẹ máa foríbalẹ̀ fún wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o má ṣe wá sãrin awọn orilẹ-ède wọnyi, awọn wọnyi ti o kù pẹlu nyin; ki ẹnyin má ṣe da orukọ oriṣa wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe fi wọn bura, ẹ má ṣe sìn wọn, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe tẹriba fun wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí ó sẹ́kù láàárin yín; ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà wọn tàbí kí ẹ fi wọ́n búra. Ẹ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n tàbí ki ẹ tẹríba fún wọn.