Joshua 23:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé, OLUWA ti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tóbi tí wọ́n sì ní agbára kúrò níwájú yín, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè ṣẹgun yín títí di òní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti OLUWA ti lé awọn orilẹ-ède nla ati alagbara kuro niwaju nyin; ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, kò sí ọkunrin kan ti o ti iduro niwaju nyin titi di oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“OLÚWA ti lé àwọn orílẹ̀ èdè ńlá àti alágbára kúrò níwájú yín; títí di òní yìí kò sí ẹnìkan tí ó le dojú kọ yín.