Joshua 24:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jóṣúà pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ ní Ṣékémù. Ó pe àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, onídájọ́ àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run.