Joshua 24:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù OLÚWA, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò àti ní Éjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin OLÚWA.