Joshua 24:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin OLÚWA nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò, tàbí òrìṣà àwọn ará Ámórì, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, OLÚWA ni àwa yóò máa sìn.”