Joshua 24:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLÚWA ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run yín.”