Joshua 24:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egungun Josefu, ti awọn ọmọ Israeli gbé gòke lati Egipti wá, ni nwọn si sin ni Ṣekemu, ni ipín ilẹ ti Jakobu rà lọwọ awọn ọmọ Hamori baba Ṣekemu li ọgọrun owo: o si di ilẹ-iní awọn ọmọ Josefu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Egungun Jóṣéfù, èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Éjíbítì, ni wọ́n sin ní Ṣékémù ní ìpín ilẹ̀ tí Jákọ́bù rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hámórì, baba Ṣékémù. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀-ìní àwọn ọmọ Jósẹ́fù.