Joshua 24:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eleasari ọmọ Aaroni si kú; nwọn si sin i li òke Finehasi ọmọ rẹ̀, ti a fi fun u li òke Efraimu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Élíásérì ọmọ Árónì sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gíbéà, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Fínéhásì ní òkè ilẹ̀ Éfúráímù.