Joshua 24:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Nígbà náà ni mo rán Mósè àti Árónì, mo sì yọ Éjíbítì lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde.