Joshua 24:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Éjíbítì, ẹ wá sí òkun, àwọn ará Éjíbítì lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun pupa.