Joshua 24:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn baba yín ké pe OLUWA, OLUWA fi òkùnkùn sí ààrin ẹ̀yin ati àwọn ará Ijipti, ó sì mú kí òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin náà ṣá fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ijipti. “ ‘Ẹ wà ninu aṣálẹ̀ fún ìgbà pípẹ́,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe OLÚWA fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́.