Joshua 3:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbéra ní Akasia lọ sí etí odò Jọdani, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀ kí wọn tó la odò náà kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Jóṣúà ati gbogbo àwọn Ísírẹ́lì sí kúrò ní Sítímù, wọ́n sì lọ sí etí odò Jọ́dánì, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá.