Joshua 3:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹsẹ̀ àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gbogbo ayé bá kan odò Jọdani, odò náà yóo dúró; kò ní ṣàn mọ́, gbogbo omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè yóo sì wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, lojukanna bi atẹlẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti OLUWA, Oluwa gbogbo aiye, ba ti tẹ̀ omi Jordani, omi Jordani yio ke kuro, ani omi ti nti òke ṣànwá; yio si duro bi òkiti kan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí OLÚWA, OLÚWA gbogbo ayé bá ti ẹṣẹ̀ bọ odò Jọ́dánì, omi tí ń ti òkè sàn wá yóò gé kúrò yóò sì gbájọ bí òkítì kan.”