Joshua 3:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
(àkókò náà jẹ́ àkókò ìkórè, odò Jọdani sì kún dé ẹnu), ṣugbọn bí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu ti dé etídò náà, tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ wọn kan omi,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ti o rù apoti si ti dé Jordani, ti awọn alufa ti o rù apoti na si tẹ̀ ẹsẹ̀ wọn bọ̀ eti omi na, (nitoripe odò Jordani a ma kún bò gbogbo bèbe rẹ̀ ni gbogbo akokò ikore,)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Odò Jọ́dánì sì máa ń wà ní kíkún ní gbogbo ìgbà ìkórè. Ṣùgbọ́n bí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí ti dé odò Jọ́dánì, tí ẹṣẹ̀ wọn sì kan etí omi,