Joshua 3:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni omi ti nti oke ṣàn wá duro, o si ga jìna rére bi òkiti li ọnà ni ilu Adamu, ti o wà lẹba Saretani: eyiti o si ṣàn sodò si ìha okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀, a ke wọn kuro patapata: awọn enia si gòke tàra si Jeriko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
omi tí ń ti òkè sàn wá dúró. Ó sì gbájọ bí òkítì ní òkèèrè, ní ìlú tí a ń pè ní Ádámù, tí ó wà ní tòsí Sárétanì; nígbà tí omi tí ń ṣàn lọ sínú òkun aginjù, (Òkun Iyọ̀) gé kúrò pátapáta. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kọjá sí òdì kejì ní ìdojúkọ Jẹ́ríkò.