Joshua 3:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kọjá lọ lórí ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn alufaa tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA dúró lórí ilẹ̀ gbígbẹ láàrin odò Jọdani, títí tí gbogbo àwọn eniyan náà fi la odò Jọdani kọjá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA, si duro ṣinṣin lori ilẹ gbigbẹ lãrin Jordani, ati gbogbo awọn enia Israeli kọja lori ilẹ gbigbẹ, titi gbogbo awọn enia na fi gòke Jordani tán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí OLÚWA sì dúró ṣinṣin lórí ilẹ̀ gbígbẹ ní àárin Jọ́dánì, nígbà tí gbógbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kọjá títí gbogbo orílẹ̀ èdè náà fi ré kọjá nínú odò Jọ́dánì lórí ilẹ̀ gbígbẹ.