Joshua 3:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Lónìí ni n óo bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ ga lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n lè mọ̀ pé bí mo ti wà pẹlu Mose, bẹ́ẹ̀ ni n óo wà pẹlu rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wi fun Joṣua pe, Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi gbé ọ ga li oju gbogbo Israeli, ki nwọn ki o le mọ̀ pe, gẹgẹ bi mo ti wà pẹlu Mose, bẹ̃li emi o wà pẹlu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì sọ fún Jóṣúà pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Ísírẹ́lì; kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lúù rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Móṣè.