Joshua 4:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé àwọn alufaa tí ó gbé Àpótí Majẹmu OLUWA dúró láàrin odò Jọdani, títí tí àwọn eniyan náà fi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ pé kí Joṣua sọ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti awọn alufa ti o rù apoti na duro lãrin Jordani, titi ohun gbogbo fi pari ti OLUWA palaṣẹ fun Joṣua lati sọ fun awọn enia, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Mose palaṣẹ fun Joṣua: awọn enia na si yára nwọn si rekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárin Jọ́dánì títí gbogbo nǹkan tí OLÚWA pa láṣẹ Jóṣúà di síṣe ní paṣẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún Jóṣúà. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,