Joshua 4:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Aré ni àwọn eniyan náà sá gun òkè odò Jọdani. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn ti gun òkè odò tan, àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA gòkè odò tẹ̀lé wọn, wọ́n sì rékọjá lọ siwaju wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia na rekọja tán, ni apoti OLUWA rekọja, ati awọn alufa, li oju awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí OLÚWA àti àwọn àlùfáà wá sí òdì kejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n.