Joshua 4:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu OLUWA jáde kúrò ninu odò Jọdani, bí wọ́n ti ń gbé ẹsẹ̀ lé ilẹ̀ gbígbẹ, ni omi odò náà pada sí ààyè rẹ̀. Odò náà sì kún bo gbogbo bèbè rẹ̀, bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati awọn alufa ti o rù apoti majẹmu OLUWA ti ãrin Jordani jade, ti awọn alufa si gbé atẹlẹsẹ̀ wọn soke si ilẹ gbigbẹ, ni omi Jordani pada si ipò rẹ̀, o si ṣàn bò gbogbo bèbe rẹ̀, gẹgẹ bi ti iṣaju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú apòtí ẹ̀rí ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹṣẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jọ́dánì náà padà sí àyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìn wá.