Joshua 4:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kinni ni àwọn eniyan náà gun òkè odò Jọdani. Wọ́n pàgọ́ sí Giligali ní ìhà ìlà oòrùn Jẹriko.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia si ti inu Jordani gòke ni ijọ́ kẹwa oṣù kini, nwọn si dó ni Gilgali, ni ìha ìla-õrùn Jeriko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹwàá (10) osù kìn-ní-ní (1) àwọn ènìyàn náà lọ láti Jọ́dánì, wọ́n sì dúró ní Gílígálì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.