Joshua 4:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, sí ààrin odò Jọdani, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan sì gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká rẹ̀. Kí iye òkúta tí ẹ óo gbé jẹ́ iye ẹ̀yà tí ó wà ninu àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ kọja lọ niwaju apoti OLUWA Ọlọrun nyin si ãrin Jordani, ki olukuluku ninu nyin ki o gbé okuta kọkan lé ejika rẹ̀, gẹgẹ bi iye ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kọjá lọ ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA Ọlọ́run yín sí àárin odò Jọ́dánì. Kí olúkúlùkù yín gbé òkúta kọ̀ọ̀kan lé èjìká a rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí iye ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,