Joshua 4:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà, ẹ óo dá wọn lóhùn pé omi odò Jọdani pín sí meji níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA nígbà tí wọn gbé e kọjá odò náà. Nítorí náà, àwọn òkúta wọnyi yóo jẹ́ ohun ìrántí ayérayé fún àwọn ọmọ Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li ẹnyin o da wọn lohùn pe, Nitori a ke omi Jordani niwaju apoti majẹmu OLUWA; nigbati o rekọja Jordani, a ke omi Jordani kuro: okuta wọnyi yio si jasi iranti fun awọn ọmọ Israeli lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò dá wọn lóhùn pé, nítorí a gé omi odò Jọ́dánì kúrò ní iwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA. Nígbà tí a rékọjá a Jọ́dánì, a gé omi Jọ́dáni kúrò. Àwọn òkúta wọ̀nyí yóò sì jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láéláé.”