Joshua 4:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joṣua to òkúta mejila mìíràn jọ láàrin odò Jọdani lọ́gangan ibi tí àwọn alufaa tí wọ́n gbé Àpótí Majẹmu dúró sí; àwọn òkúta náà wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si tò okuta mejila jọ lãrin Jordani, ni ibi ti ẹsẹ̀ awọn alufa ti o rù apoti majẹmu na gbé duro: nwọn si mbẹ nibẹ̀ titi di oni-oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóṣúà sì to òkúta méjìlá (12) náà sí àárin odò Jọ́dánì fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.