Joshua 5:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Amori, tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani, ati gbogbo ọba àwọn ará ilẹ̀ Kenaani, tí wọ́n wà ní etí Òkun gbọ́ pé OLUWA mú kí odò Jọdani gbẹ nítorí àwọn ọmọ Israẹli, títí tí wọ́n fi rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, àyà wọn já, ìdààmú sì bá wọn, nítorí àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ọba Amori, ti o wà ni ìha keji Jordani ni ìwọ-õrùn, ati gbogbo awọn ọba Kenaani ti mbẹ leti okun, gbọ́ pe OLUWA ti mu omi Jordani gbẹ kuro niwaju awọn ọmọ Israeli, titi awa fi là a kọja, ni àiya wọn já, bẹ̃li ẹmi kò sí ninu wọn mọ́, nitori awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo àwọn ọba Ámórì ti ìlà-oòrùn Jọ́dánì àti gbogbo àwọn ọba Kénánì tí ń bẹ létí òkun gbọ́ bí OLÚWA ti mú Jọ́dánì gbẹ ní iwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí ti a fi kọjá, ọkàn wọn pámi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ìgboyà mọ́ láti dojú kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.