Joshua 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òwúrọ̀ ọjọ́ keji lẹ́yìn àjọ ìrékọjá ni ìgbà kinni tí wọ́n fi ẹnu kàn ninu èso ilẹ̀ náà, wọ́n jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà ati ọkà gbígbẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si jẹ ọkà gbigbẹ ilẹ na ni ijọ́ keji lẹhin irekọja, àkara alaiwu, ọkà didin li ọjọ̀ na gan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kéjì Àjọ-ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan-an ni, wọ́n jẹ nínú; àwọn irè oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.