Joshua 5:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mana kò dà ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, àwọn ọmọ Israẹli kò rí i kó mọ́, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ ninu èso ilẹ̀ náà. Ṣugbọn wọ́n jẹ ninu èso ilẹ̀ Kenaani ní gbogbo ọdún náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Manna si dá ni ijọ́ keji lẹhin igbati nwọn ti jẹ okà gbigbẹ ilẹ na; awọn ọmọ Israeli kò si ri manna mọ́; ṣugbọn nwọn jẹ eso ilẹ Kenaani li ọdún na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mánà náà sì tan ní ọjọ́ kéjì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde; kò sì sí mánà kankan mọ́ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ irè oko ilẹ̀ Kénánì.