Joshua 5:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati Joṣua wà leti Jeriko, o gbé oju rẹ̀ soke o si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan duro niwaju rẹ̀ pẹlu idà fifayọ li ọwọ́ rẹ̀: Joṣua si tọ̀ ọ lọ, o si wi fun u pe, Ti wa ni iwọ nṣe, tabi ti ọtá wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Jóṣúà sún mọ́ Jẹ́ríkò, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Jóṣúà sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀ta a wa?”