Joshua 5:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí tí Joṣua fi kọ ilà abẹ́ fún wọn ni pé, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ti kú lójú ọ̀nà ninu aṣálẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde láti ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idí rẹ̀ li eyi ti Joṣua fi kọ wọn nilà: gbogbo awọn enia ti o ti Egipti jade wá, ti o ṣe ọkunrin, ani gbogbo awọn ọmọ-ogun, nwọn kú li aginjù, li ọ̀na, lẹhin igbati nwọn jade kuro ni Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wàyí o, ìdí tí Jóṣúà fi kọ wọ́n nílà nìyìí: Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó ti Éjíbítì jáde wá, gbogbo àwọn ọkùnrin ogun kú ní asálẹ̀ ní ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.