Joshua 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ogoji ọdún ni àwọn ọmọ Israẹli fi ń rìn kiri láàrin aṣálẹ̀, títí tí àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jagun, tí wọ́n jáde láti Ijipti fi parun tán, nítorí wọn kò gbọ́ ti OLUWA wọn. OLUWA sì ti búra pé, òun kò ní jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ tí òun ti búra láti fún àwọn baba wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Ísírẹ́lì rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Éjíbítì fi kú, nítorí wọn kò gbọ́ràn sí OLÚWA. Nítorí OLÚWA ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fí fun wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.