Joshua 5:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eniyan náà kọ ilà abẹ́ tán, olukuluku wà ní ààyè rẹ̀ ninu àgọ́ títí egbò wọn fi jinná.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati nwọn kọ gbogbo awọn enia na nilà tán, nwọn joko ni ipò wọn ni ibudó, titi ara wọn fi dá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀ èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná.