Joshua 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awọn enia na hó, nigbati awọn alufa fọn ipè: o si ṣe, nigbati awọn enia gbọ́ iró ipè, ti awọn enia si hó kũ, odi na wólulẹ bẹrẹ, bẹ̃li awọn enia wọ̀ inu ilu na lọ, olukuluku tàra niwaju rẹ̀, nwọn si kó ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn àlùfáà fọn ìpè, àwọn ènìyàn náà sì hó Ó sì ṣe, bí àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìró ìpè, tí àwọn ènìyàn sì hó ìhó-ńlá, odi ìlú náà wó lulẹ̀ bẹẹrẹ; bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ya wọ inú ìlú náà lọ tààrà, wọ́n sì kó ìlú náà.