Joshua 7:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Israẹli dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA nítorí pé ẹnìkan mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀. Akani ọmọ Karimi, ọmọ Sabidi, ọmọ Sera, láti inú ẹ̀yà Juda, mú ninu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀, inú sì bí OLUWA gidigidi sí àwọn ọmọ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàṣọ́tọ̀, Ákánì ọmọ Kámì, ọmọ Símírì, ọmọ Ṣérà, ẹ̀yà Júdà, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú OLÚWA ru sí àwọn ará Ísírẹ́lì.