Joshua 7:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n sá níwájú àwọn ọ̀tá wọn nítorí pé, wọ́n ti di ẹni ìparun. N kò ní wà pẹlu yín mọ́, àfi bí ẹ bá run àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ tí ó wà láàrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí nì-yí tí àwọn ará Ísírẹ́lì kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀ta wọn; wọ́n yí ẹ̀yín wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀ta a wọn nítorí pé àwọn gan-an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò se pé ẹ̀yin pa ohun ìyàṣọ́tọ̀ run kúrò ní àárin yín.