Joshua 7:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, a óo mú gbogbo yín wá siwaju OLUWA ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; ẹ̀yà tí OLUWA bá mú yóo wá ní agbo-ilé agbo-ilé. Agbo-ilé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ìdílé-ìdílé. Àwọn ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé tí OLUWA bá mú yóo wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ní òwúrọ̀ kí ẹ mú ará yín wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí OLÚWA bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí OLÚWA bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí OLÚWA bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan.