Joshua 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá mú pẹlu àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, iná ni a óo dá sun àtòun, ati gbogbo nǹkan tí ó ní, nítorí pé ó ti ṣẹ̀ sí majẹmu OLUWA. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú OLÚWA jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”