Joshua 7:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joṣua rán àwọn ọkunrin kan láti Jẹriko lọ sí ìlú Ai, lẹ́bàá Betafeni ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe amí ilẹ̀ náà wá.” Àwọn ọkunrin náà lọ ṣe amí ìlú Ai.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jóṣúà rán àwọn ọkùnrin láti Jẹ́ríkò lọ sí Áì, tí ó sún mọ́ Bẹti-Áfẹ́nì ní ìlà-oòrùn Bétélì, ó sì sọ fún wọn pé, “Ẹ gòkè lọ kí ẹ sì ṣe amí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn arákùnrin náà lọ, wọ́n sì yọ́ Áì wò.