Joshua 7:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí mo wo ààrin àwọn ìkógun, mo rí ẹ̀wù àwọ̀lékè dáradára kan láti Ṣinari, ati igba ìwọ̀n Ṣekeli fadaka, ati ọ̀pá wúrà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọta Ṣekeli, wọ́n wọ̀ mí lójú, mo bá kó wọn, mo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ ninu àgọ́ mi. Fadaka ni mo fi tẹ́lẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Bábílónì kan tí ó dára nínú ìkógún, àti igba sẹ́kélì fàdákà àti díndi wúrà olóṣùnwọ̀n àádọ́ta ṣẹ́kélì, mo ṣe ojú kòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ ọ̀ mi àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀.”