Joshua 7:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósúà sì fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì dojú bolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí OLÚWA títí di àṣálẹ́. Àwọn àgbà Ísírẹ́lì sì ṣe bákan náà, wọ́n ku eruku sí orí i wọn.