Joshua 7:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Joṣua bá gbadura, ó ní, “Yéè! OLUWA Ọlọrun! Kí ló dé tí o fi kó àwọn eniyan wọnyi gòkè odò Jọdani láti fà wọ́n lé àwọn ará Amori lọ́wọ́ láti pa wọ́n run? Ìbá tẹ́ wa lọ́rùn kí á wà ní òdìkejì odò Jọdani, kí á sì máa gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósúà sì wí pé, “Háà, OLÚWA Ọlọ́run alágbára, nítorí i kiín ni ìwọ ṣe mú àwọn ènìyàn yìí kọjá a Jọ́dánì, láti fi wọ́n lé àwọn ará Ámórì lọ́wọ́; láti pa wọn run? Àwa ìbá mọ̀ kí a dúró ní òdì kéjì Jọ́dánì?