Joshua 8:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá a lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìlú Ai, wọ́n sì pàgọ́ wọn sí apá ìhà àríwá ìlú náà, odò kan ni ó wà láàrin wọn ati ìlú Ai.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn enia, ani awọn ọmọ-ogun ti mbẹ pẹlu rẹ̀, nwọn gòke lọ, nwọn si sunmọtosi, nwọn si wá siwaju ilu na, nwọn si dó ni ìha ariwa Ai; afonifoji si mbẹ li agbedemeji wọn ati Ai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú u rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì súnmọ́ tòsí ìlú náà, wọ́n sì dé iwájú u rẹ̀. Wọ́n sì pàgọ́ ní ìhà àríwá Áì. Àfonífojì sì wà ní agbede-méjì wọn àti ìlú náà.