Joshua 8:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọba Ai ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ rí i, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ìlú náà bá yára, wọ́n jáde lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ apá ọ̀nà Araba láti kó ogun pàdé àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọn kò mọ̀ pé àwọn kan ti farapamọ́ sẹ́yìn ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati ọba Ai ri i, nwọn yára nwọn si dide ni kùtukutu, awọn ọkunrin ilu na si jade si Israeli lati jagun, ati on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, niwaju pẹtẹlẹ̀, ibi ti a ti yàn tẹlẹ; ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn ti o ba dè e mbẹ lẹhin ilu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọba Áì rí èyí, òun àti gbogbo ọkùnrin ìlú náà yára jáde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti pàdé ogun Ísírẹ́lì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aginjù. Ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àwọn kan wà ní ibùba ní ẹ̀yìn ìlú náà.