Joshua 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sì sí ẹyọ ọkunrin kan tí ó kù ní Ai ati Bẹtẹli tí kò jáde láti lépa àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n fi ìlẹ̀kùn ẹnubodè sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n ń lé àwọn ọmọ Israẹli lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si kù ọkunrin kan ni Ai tabi Beti-eli, ti kò jade tọ̀ Israeli: nwọn si fi ilú nla silẹ ni ṣíṣí nwọn si lepa Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sì ku ọkùnrin kan ní Áì tàbi Bétélì tí kò tẹ̀lé Ísírẹ́lì. Wọ́n sì fi ìlẹ̀kùn ibodè náà sílẹ̀ ní ṣíṣí, wọ́n sì ń lépa àwọn ará Ísírẹ́lì.